8 Yóò ní àwọn ọmọ abẹ́ láti òkun dé òkun
Àti láti Odò dé àwọn ìkángun ayé.+
9 Àwọn tó ń gbé ní aṣálẹ̀ yóò tẹrí ba níwájú rẹ̀,
Àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò sì lá erùpẹ̀.+
10 Àwọn ọba Táṣíṣì àti ti àwọn erékùṣù yóò máa san ìṣákọ́lẹ̀.+
Àwọn ọba Ṣébà àti ti Sébà yóò mú ẹ̀bùn wá.+