18 Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ kúrò* àti gbogbo àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì+ àti àwọn ará Gátì,+ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin tí wọ́n tẹ̀ lé e láti Gátì,+ sì ń kọjá bí ọba ti ń yẹ̀ wọ́n wò.*
7 Torí náà, àwọn ọkùnrin Jóábù+ àti àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì+ pẹ̀lú gbogbo àwọn alágbára ọkùnrin tẹ̀ lé e; wọ́n sì jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù láti lépa Ṣébà ọmọ Bíkíráì.