-
Diutarónómì 20:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 “Tí o bá lọ bá àwọn ọ̀tá rẹ jagun, tí o sì rí àwọn ẹṣin, àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ọmọ ogun wọn tí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ jù ọ́ lọ, má bẹ̀rù wọn, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì wà pẹ̀lú rẹ.+
-
-
Sáàmù 18:37, 38Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
37 Màá lépa àwọn ọ̀tá mi, màá sì bá wọn;
Mi ò ní pa dà títí wọ́n á fi pa rẹ́.
38 Màá fọ́ wọn túútúú, kí wọ́n má lè gbérí mọ́;+
Wọ́n á ṣubú sábẹ́ ẹsẹ̀ mi.
-