-
Jóṣúà 16:5-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ààlà àwọn àtọmọdọ́mọ Éfúrémù ní ìdílé-ìdílé nìyí: Ààlà ogún wọn lápá ìlà oòrùn ni Ataroti-ádárì+ títí dé Bẹti-hórónì Òkè,+ 6 ó sì dé òkun. Míkímẹ́tátì+ wà ní àríwá, ààlà náà sì yí gba apá ìlà oòrùn lọ sí Taanati-ṣílò, ó sì gba ìlà oòrùn lọ sí Jánóà. 7 Láti Jánóà, ó gba ìsàlẹ̀ lọ sí Átárótì àti Náárà, ó sì dé Jẹ́ríkò,+ títí lọ dé Jọ́dánì. 8 Láti Tápúà,+ ààlà náà lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn títí dé Àfonífojì Kánà, ó sì parí sí òkun.+ Èyí ni ogún ẹ̀yà Éfúrémù ní ìdílé-ìdílé;
-