5 Torí náà, Dáfídì rán àwọn òjíṣẹ́ sí àwọn ará Jabeṣi-gílíádì, ó sọ fún wọn pé: “Kí Jèhófà bù kún yín, nítorí ẹ fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Sọ́ọ̀lù, olúwa yín, ní ti pé ẹ sin ín.+ 6 Kí Jèhófà fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti ìṣòtítọ́ hàn sí yín. Èmi náà máa ṣojú rere sí yín nítorí ohun tí ẹ ṣe yìí.+