36 Nígbà náà, ọba ránṣẹ́ pe Ṣíméì,+ ó sì sọ fún un pé: “Kọ́ ilé kan fún ara rẹ ní Jerúsálẹ́mù, kí o sì máa gbé ibẹ̀; má ṣe kúrò níbẹ̀ lọ sí ibikíbi. 37 Ọjọ́ tí o bá jáde síta, tí o sì sọdá Àfonífojì Kídírónì,+ mọ̀ dájú pé wàá kú. Ẹ̀jẹ̀ rẹ á sì wà lórí ìwọ fúnra rẹ.”