18 Ọ̀kan lára àwọn ẹmẹ̀wà* sọ pé: “Wò ó! Mo ti rí bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ Jésè ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ṣe ń ta háàpù dáadáa, onígboyà ni, jagunjagun tó lákíkanjú sì ni.+ Ó mọ̀rọ̀ọ́ sọ, ó rẹwà,+ Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.”+
18 Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ kúrò* àti gbogbo àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì+ àti àwọn ará Gátì,+ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin tí wọ́n tẹ̀ lé e láti Gátì,+ sì ń kọjá bí ọba ti ń yẹ̀ wọ́n wò.*
8 Orúkọ àwọn jagunjagun Dáfídì tó lákíkanjú+ nìyí: Joṣebi-báṣébétì tó jẹ́ Tákímónì, olórí àwọn mẹ́ta náà.+ Ìgbà kan wà tó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) ọkùnrin.