-
Jóṣúà 7:24-26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì wá mú Ákánì+ ọmọ Síírà, fàdákà náà, ẹ̀wù oyè náà àti wúrà gbọọrọ náà,+ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, akọ màlúù rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, agbo ẹran rẹ̀, àgọ́ rẹ̀ àti gbogbo ohun tó jẹ́ tirẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá sí Àfonífojì* Ákórì.+ 25 Jóṣúà sọ pé: “Kí ló dé tí o fa àjálù* bá wa?+ Jèhófà máa mú àjálù bá ọ lónìí.” Ni gbogbo Ísírẹ́lì bá sọ ọ́ lókùúta,+ lẹ́yìn náà, wọ́n dáná sun wọ́n.+ Bí wọ́n ṣe sọ gbogbo wọn lókùúta nìyẹn. 26 Wọ́n kó òkúta jọ pelemọ lé e lórí, ó sì wà bẹ́ẹ̀ títí dòní. Bí inú tó ń bí Jèhófà gidigidi ṣe rọlẹ̀ nìyẹn.+ Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Àfonífojì Ákórì* títí dòní.
-