14 Lẹ́yìn náà, wọ́n sin egungun Sọ́ọ̀lù àti ti Jónátánì ọmọ rẹ̀ sí ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì ní Sẹ́là+ ní ibi tí wọ́n sin Kíṣì+ bàbá rẹ̀ sí. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe gbogbo ohun tí ọba pa láṣẹ, Ọlọ́run gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn lórí ilẹ̀ náà.+
13 Ó ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sì mú kí àánú ṣe Ọlọ́run, ó gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún ojú rere, ó sì mú un pa dà sí Jerúsálẹ́mù sí ipò ọba rẹ̀.+ Mánásè sì wá mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.+