43 Wàá gbà mí lọ́wọ́ àwọn èèyàn tó ń wá àléébù.+
Wàá yàn mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè.+
Àwọn èèyàn tí mi ò mọ̀ yóò sìn mí.+
44 Ohun tí wọ́n bá gbọ́ nìkan yóò mú kí wọ́n ṣègbọràn sí mi;
Àwọn àjèjì á wá ba búrúbúrú níwájú mi.+
45 Ọkàn àwọn àjèjì á domi;
Wọ́n á jáde tẹ̀rùtẹ̀rù látinú ibi ààbò wọn.