44 Wàá gbà mí lọ́wọ́ àwọn èèyàn mi tó ń wá àléébù.+
Wàá ṣọ́ mi kí n lè di olórí àwọn orílẹ̀-èdè;+
Àwọn èèyàn tí mi ò mọ̀ yóò sìn mí.+
45 Àwọn àjèjì á wá ba búrúbúrú níwájú mi;+
Ohun tí wọ́n bá gbọ́ nípa mi á mú kí wọ́n ṣègbọràn sí mi.
46 Ọkàn àwọn àjèjì á domi;
Wọ́n á jáde tẹ̀rùtẹ̀rù látinú ibi ààbò wọn.