ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Onídàájọ́ 15:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Nígbà tó dé Léhì, àwọn Filísínì kígbe ayọ̀ bí wọ́n ṣe rí i. Nígbà náà, ẹ̀mí Jèhófà fún un lágbára,+ àwọn okùn tí wọ́n fi de ọwọ́ rẹ̀ wá dà bíi fọ́nrán òwú ọ̀gbọ̀ tí iná jó gbẹ, àwọn ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ sì yọ́.+

  • Àwọn Onídàájọ́ 15:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Sámúsìn wá sọ pé:

      “Pẹ̀lú egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, òkìtì kan, òkìtì méjì!

      Mo fi egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ṣá ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin balẹ̀.”+

  • 1 Sámúẹ́lì 14:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Nítorí náà, Jónátánì sọ fún ìránṣẹ́ tó ń bá a gbé ìhámọ́ra pé: “Wá, jẹ́ ká sọdá lọ sọ́dọ̀ àwùjọ ọmọ ogun aláìdádọ̀dọ́*+ tó wà ní àdádó yìí. Bóyá Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́, nítorí kò sí ohun tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ láti gbani là, ì báà jẹ́ nípasẹ̀ àwọn tó pọ̀ tàbí àwọn díẹ̀.”+

  • 1 Sámúẹ́lì 19:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wewu* kó lè pa Filísínì náà,+ tí Jèhófà sì mú kí gbogbo Ísírẹ́lì ṣẹ́gun* lọ́nà tó kàmàmà. O rí i, inú rẹ sì dùn gan-an. Kí ló wá dé tí o fẹ́ fi pa Dáfídì láìnídìí, tí wàá sì ní ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ lọ́rùn?”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́