ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jóṣúà 15:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Ilẹ̀ tí wọ́n pín+ fún ẹ̀yà Júdà ní ìdílé-ìdílé lọ dé ààlà Édómù,+ aginjù Síínì, dé ìpẹ̀kun Négébù lápá gúúsù.

  • Jóṣúà 15:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Ààlà náà dé Àfonífojì Ọmọ Hínómù,+ ó dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn ará Jébúsì+ ní gúúsù, ìyẹn Jerúsálẹ́mù,+ ààlà náà dé orí òkè tó dojú kọ Àfonífojì Hínómù lápá ìwọ̀ oòrùn, èyí tó wà ní ìkángun Àfonífojì* Réfáímù lápá àríwá.

  • 2 Sámúẹ́lì 5:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Nígbà tó yá, àwọn Filísínì tún wá, wọ́n sì dúró káàkiri Àfonífojì* Réfáímù.+

  • 1 Kíróníkà 11:15-19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Mẹ́ta lára ọgbọ̀n (30) ọkùnrin tó jẹ́ olórí lọ sí ibi àpáta lọ́dọ̀ Dáfídì ní ihò àpáta Ádúlámù,+ lákòókò yìí, àwùjọ àwọn ọmọ ogun Filísínì kan pàgọ́ sí Àfonífojì* Réfáímù.+ 16 Nígbà yẹn, Dáfídì wà ní ibi ààbò, àwùjọ ọmọ ogun Filísínì tó wà ní àdádó sì wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. 17 Lẹ́yìn náà, Dáfídì sọ ohun tó ń wù ú, ó ní: “Ì bá dára ká ní mo lè rí omi mu láti inú kòtò omi tó wà ní ẹnubodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù!”+ 18 Ni àwọn mẹ́ta náà bá fipá wọnú ibùdó àwọn Filísínì, wọ́n fa omi láti inú kòtò omi tó wà ní ẹnubodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, wọ́n sì gbé e wá fún Dáfídì; àmọ́ Dáfídì kọ̀, kò mu ún, ńṣe ló dà á jáde fún Jèhófà. 19 Ó sọ pé: “Ọlọ́run ò gbọ́dọ̀ gbọ́ pé mo ṣe nǹkan yìí! Ṣé ó yẹ kí n mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkùnrin tó fẹ̀mí*+ ara wọn wewu yìí? Nítorí ẹ̀mí* wọn ni wọ́n fi wewu kí wọ́n lè gbé e wá.” Torí náà, ó kọ̀, kò mu ún. Àwọn ohun tí àwọn jagunjagun rẹ̀ mẹ́ta tó lákíkanjú ṣe nìyẹn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́