-
1 Kíróníkà 21:24-28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Àmọ́, Ọba Dáfídì sọ fún Ọ́nánì pé: “Rárá o, iye tó bá jẹ́ ni màá rà á, torí mi ò ní gba ohun tó jẹ́ tìrẹ kì n sì fún Jèhófà tàbí kí n fi rú àwọn ẹbọ sísun láìná nǹkan kan.”+ 25 Nítorí náà, Dáfídì fún Ọ́nánì ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ṣékélì* wúrà fún ilẹ̀ náà. 26 Dáfídì mọ pẹpẹ kan+ síbẹ̀ fún Jèhófà, ó sì rú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀, ó ké pe Jèhófà, ẹni tó wá fi iná dá a lóhùn+ láti ọ̀run sórí pẹpẹ ẹbọ sísun náà. 27 Lẹ́yìn náà, Jèhófà pàṣẹ fún áńgẹ́lì+ náà pé kí ó dá idà rẹ̀ pa dà sínú àkọ̀ rẹ̀. 28 Lákòókò yẹn, nígbà tí Dáfídì rí i pé Jèhófà ti dá òun lóhùn ní ibi ìpakà Ọ́nánì ará Jébúsì, ó ń rúbọ níbẹ̀ nìṣó.
-