15 Ní báyìí, kí olúwa mi fi àlìkámà, ọkà bálì, òróró àti wáìnì tó ṣèlérí ránṣẹ́ sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+ 16 A máa gé àwọn igi láti Lẹ́bánónì,+ bí èyí tí o nílò bá ṣe pọ̀ tó, a ó kó wọn wá sọ́dọ̀ rẹ ní àdìpọ̀ igi tó léfòó, a ó sì kó wọn gba orí òkun wá sí Jópà;+ wàá sì kó wọn lọ sí Jerúsálẹ́mù.”+