-
2 Sámúẹ́lì 8:10-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Torí náà, Tóì rán Jórámù ọmọkùnrin rẹ̀ sí Ọba Dáfídì pé kí ó lọ béèrè àlàáfíà rẹ̀, kí ó sì bá a yọ̀ torí pé ó ti bá Hadadésà jà, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ (nítorí Hadadésà ti máa ń bá Tóì jà tẹ́lẹ̀), ó sì kó àwọn ohun èlò fàdákà, ohun èlò wúrà àti ohun èlò bàbà wá. 11 Ọba Dáfídì yà wọ́n sí mímọ́ fún Jèhófà bó ṣe ya fàdákà àti wúrà tó kó lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tó ti ṣẹ́gun+ sí mímọ́: 12 ó kó wọn láti Síríà àti Móábù,+ látọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì, àwọn Filísínì+ àti àwọn ọmọ Ámálékì+ àti látinú ẹrù ogun Hadadésà+ ọmọ Réhóbù ọba Sóbà.
-