2 Ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì pe àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, gbogbo olórí àwọn ẹ̀yà àti àwọn olórí agbo ilé ní Ísírẹ́lì. Wọ́n wá sí Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n lè gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà láti Ìlú Dáfídì,+ ìyẹn Síónì.+ 3 Gbogbo èèyàn Ísírẹ́lì pé jọ síwájú ọba nígbà àjọyọ̀ tí wọ́n ń ṣe ní oṣù keje.+