-
1 Àwọn Ọba 8:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì pe àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ,+ gbogbo olórí àwọn ẹ̀yà àti àwọn olórí agbo ilé ní Ísírẹ́lì.+ Wọ́n wá sọ́dọ̀ Ọba Sólómọ́nì ní Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n lè gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà láti Ìlú Dáfídì,+ ìyẹn Síónì.+ 2 Gbogbo èèyàn Ísírẹ́lì pé jọ síwájú Ọba Sólómọ́nì nígbà àjọyọ̀* ní oṣù Étánímù,* ìyẹn oṣù keje.+
-