33 Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn tó ni ín sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ fi ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yẹn?” 34 Wọ́n sọ pé: “Olúwa fẹ́ lò ó.” 35 Wọ́n wá mú un lọ sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n ju aṣọ àwọ̀lékè wọn sórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n sì mú kí Jésù jókòó sórí rẹ̀.+