3 Sámúẹ́lì sì sọ fún gbogbo ilé Ísírẹ́lì pé: “Bí ẹ bá máa fi gbogbo ọkàn yín pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà,+ ẹ mú àwọn ọlọ́run àjèjì+ àti àwọn ère Áṣítórétì+ kúrò láàárín yín, kí ẹ sì darí ọkàn yín tààrà sọ́dọ̀ Jèhófà, kí ẹ máa sin òun nìkan ṣoṣo,+ yóò sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn Filísínì.”+