5Nígbà tí Hírámù ọba Tírè+ gbọ́ pé a ti fòróró yan Sólómọ́nì láti jọba ní ipò bàbá rẹ̀, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí Sólómọ́nì, nítorí tipẹ́tipẹ́ ni Hírámù ti jẹ́ ọ̀rẹ́* Dáfídì.+
7 Nígbà tí Hírámù gbọ́ ohun tí Sólómọ́nì sọ, inú rẹ̀ dùn gan-an, ó sì sọ pé: “Ìyìn ni fún Jèhófà lónìí, nítorí ó ti fún Dáfídì ní ọlọ́gbọ́n ọmọ tó máa darí ọ̀pọ̀ èèyàn* yìí!”+