20 Gbàrà tí gbogbo Ísírẹ́lì gbọ́ pé Jèróbóámù ti pa dà dé, wọ́n pè é wá sí àpéjọ, wọ́n sì fi jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.+ Kò sí ìkankan lára àwọn èèyàn náà tó wà lẹ́yìn ilé Dáfídì àfi ẹ̀yà Júdà.+
11Nígbà tí Rèhóbóámù dé Jerúsálẹ́mù, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló pe ilé Júdà àti Bẹ́ńjámínì+ jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) akọgun,* láti bá Ísírẹ́lì jà, kí wọ́n lè gba ìjọba pa dà fún Rèhóbóámù.+