-
1 Àwọn Ọba 9:4, 5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Ní tìrẹ, tí o bá rìn níwájú mi bí Dáfídì bàbá rẹ ṣe rìn+ pẹ̀lú òtítọ́ ọkàn+ àti ìdúróṣinṣin,+ tí ò ń ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ,+ tí o sì ń pa àwọn ìlànà mi àti àwọn ìdájọ́ mi mọ́,+ 5 ìgbà náà ni màá fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ lórí Ísírẹ́lì múlẹ̀ títí láé, bí mo ti ṣèlérí fún Dáfídì bàbá rẹ pé, ‘Kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ tí yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.’+
-
-
Sáàmù 89:49Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
49 Jèhófà, ibo ni ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ti ìgbà àtijọ́ wà,
Èyí tí o búra nípa rẹ̀ fún Dáfídì nínú òtítọ́ rẹ?+
-