ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 6:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ+ àti gbogbo okun rẹ*+ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.

  • 2 Àwọn Ọba 20:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 “Mo bẹ̀ ọ́, Jèhófà, jọ̀ọ́ rántí bí mo ṣe fi òtítọ́ àti gbogbo ọkàn mi rìn níwájú rẹ, ohun tó dáa ní ojú rẹ sì ni mo ṣe.”+ Hẹsikáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀.

  • 2 Àwọn Ọba 23:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Ọba dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó, ó sì dá májẹ̀mú* níwájú Jèhófà+ pé gbogbo ọkàn àti gbogbo ara* ni òun á máa fi tẹ̀ lé Jèhófà, òun á sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ àti àwọn ìránnilétí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀, láti máa ṣe ohun tí májẹ̀mú tí a kọ sínú ìwé yìí sọ. Gbogbo àwọn èèyàn náà sì fara mọ́ májẹ̀mú náà.+

  • 2 Kíróníkà 17:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Jèhófà wà pẹ̀lú Jèhóṣáfátì nítorí pé ó rìn ní àwọn ọ̀nà tí Dáfídì+ baba ńlá rẹ̀ rìn nígbà àtijọ́, kò sì wá àwọn Báálì.

  • Mátíù 22:37
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 37 Ó sọ fún un pé: “‘Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà* Ọlọ́run rẹ.’+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́