3 Nítorí náà, Ábíjà kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) àwọn ọmọ ogun tí wọ́n lákíkanjú, tí wọ́n sì jẹ́ akọgun lọ sójú ogun.+ Bákan náà, Jèróbóámù kó ogójì ọ̀kẹ́ (800,000) àwọn ọkùnrin tó mọṣẹ́ ogun, àwọn jagunjagun tó lákíkanjú, ó sì tò wọ́n lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti dojú kọ ọ́.