ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 23:17, 18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 “Ìkankan nínú àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ di aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì,+ bẹ́ẹ̀ ni ìkankan nínú àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ di aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì.+ 18 O ò gbọ́dọ̀ mú owó tí wọ́n san fún obìnrin kan nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó tàbí owó tí wọ́n san fún ọkùnrin kan* nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó* wá sínú ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ láti fi san ẹ̀jẹ́, torí méjèèjì jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.

  • 1 Àwọn Ọba 15:11, 12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Ásà ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà,+ bíi Dáfídì baba ńlá rẹ̀. 12 Ó lé àwọn aṣẹ́wó ọkùnrin tó wà ní tẹ́ńpìlì kúrò ní ilẹ̀ náà,+ ó sì mú gbogbo òrìṣà ẹ̀gbin* tí àwọn baba ńlá rẹ̀ ṣe kúrò.+

  • 1 Àwọn Ọba 22:46
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 46 Ó tún lé ìyókù àwọn aṣẹ́wó ọkùnrin tó wà ní tẹ́ńpìlì+ jáde ní ilẹ̀ náà, ìyẹn àwọn tó ṣẹ́ kù nígbà ayé Ásà bàbá rẹ̀.+

  • 2 Àwọn Ọba 23:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Ó tún wó àwọn ilé aṣẹ́wó ọkùnrin+ tó wà ní tẹ́ńpìlì, èyí tó wà nínú ilé Jèhófà àti ibi tí àwọn obìnrin ti ń hun aṣọ àgọ́ fún ojúbọ òpó òrìṣà.*

  • Hósíà 4:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Èmi kì yóò mú kí àwọn ọmọbìnrin yín jíhìn torí pé wọ́n ṣe ìṣekúṣe*

      Àti aya àwọn ọmọ yín torí pé wọ́n ṣe àgbèrè.

      Nítorí pé àwọn ọkùnrin yín ń bá àwọn aṣẹ́wó kẹ́gbẹ́

      Wọ́n sì ń rúbọ pẹ̀lú àwọn aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì;

      Àwọn èèyàn tí kò lóye+ yìí yóò pa run.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́