ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 32:39
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  39 Ẹ rí i báyìí pé èmi, àní èmi ni ẹni náà,+

      Kò sí ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.+

      Mo lè pani, mo sì lè sọni di alààyè.+

      Mo lè dá ọgbẹ́+ síni lára, mo sì lè woni sàn,+

      Kò sí ẹnì kankan tó lè gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ mi.+

  • 1 Sámúẹ́lì 2:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Jèhófà ń pani, ó sì ń dá ẹ̀mí ẹni sí;*

      Ó múni sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú Isà Òkú,* ó sì ń gbéni dìde.+

  • 2 Àwọn Ọba 4:32
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 32 Nígbà tí Èlíṣà wọnú ilé náà, òkú ọmọ náà wà lórí ibùsùn rẹ̀.+

  • 2 Àwọn Ọba 4:34
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 34 Ó gorí ibùsùn, ó nà lé ọmọ náà, ó sì gbé ẹnu rẹ̀ lé ẹnu ọmọ náà àti ojú rẹ̀ lé ojú ọmọ náà, ó tún gbé àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ lé àtẹ́lẹwọ́ ọmọ náà, ó sì nà lé e lórí síbẹ̀, ara ọmọ náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í móoru.+

  • 2 Àwọn Ọba 13:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Lọ́jọ́ kan, bí àwọn kan ṣe fẹ́ máa sin òkú ọkùnrin kan, wọ́n rí àwọn jàǹdùkú* náà, wọ́n bá sáré ju òkú ọkùnrin náà sínú ibojì Èlíṣà, wọ́n sì sá lọ. Nígbà tí òkú ọkùnrin náà fara kan egungun Èlíṣà, ó jí dìde,+ ó sì dìde dúró.

  • Lúùkù 7:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Ọkùnrin tó ti kú náà wá dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, Jésù sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.+

  • Lúùkù 8:54, 55
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 54 Àmọ́ ó dì í lọ́wọ́ mú, ó sì pè é, ó ní: “Ọmọ, dìde!”+ 55 Ẹ̀mí rẹ̀*+ sì pa dà, ó dìde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀,+ ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n fún un ní nǹkan tó máa jẹ.

  • Jòhánù 5:28, 29
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 Ẹ má ṣe jẹ́ kí èyí yà yín lẹ́nu, torí wákàtí náà ń bọ̀, tí gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí máa gbọ́ ohùn rẹ̀,+ 29 tí wọ́n á sì jáde wá, àwọn tó ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè, àwọn tó sọ ohun burúkú dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.+

  • Jòhánù 11:44
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 44 Ọkùnrin tó ti kú náà jáde wá, tòun ti aṣọ tí wọ́n fi dì í tọwọ́tẹsẹ̀ àti aṣọ tí wọ́n fi di ojú rẹ̀. Jésù sì sọ fún wọn pé: “Ẹ tú u, kí ẹ jẹ́ kó máa lọ.”

  • Ìṣe 9:40, 41
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 40 Pétérù wá ní kí gbogbo èèyàn bọ́ síta,+ ó kúnlẹ̀, ó sì gbàdúrà. Lẹ́yìn náà, ó yíjú sí òkú náà, ó sọ pé: “Tàbítà, dìde!” Obìnrin náà lajú, bó ṣe tajú kán rí Pétérù, ó dìde jókòó.+ 41 Pétérù na ọwọ́ sí i, ó gbé e dìde, ó sì pe àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn opó, ó wá fà á lé wọn lọ́wọ́ láàyè.+

  • Ìṣe 20:9, 10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Yútíkọ́sì jókòó sójú fèrèsé,* ó sùn lọ fọnfọn nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, oorun ti gbé e lọ, ló bá ṣubú láti àjà kẹta, ó sì ti kú nígbà tí wọ́n fi máa gbé e. 10 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù lọ sísàlẹ̀, ó dùbúlẹ̀ lé e, ó sì gbá a mọ́ra,+ ó sọ pé: “Ẹ dákẹ́ ariwo, torí ó ti jí.”*+

  • Róòmù 14:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Torí èyí ni Kristi fi kú, tí ó sì pa dà wà láàyè, kí ó lè jẹ́ Olúwa lórí àwọn òkú àti àwọn alààyè.+

  • Hébérù 11:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Nígbà tí a dán Ábúráhámù wò,+ ká kúkú sọ pé ó ti fi Ísákì rúbọ tán torí ìgbàgbọ́—ọkùnrin tó gba àwọn ìlérí náà tayọ̀tayọ̀ fẹ́ fi ọmọkùnrin kan ṣoṣo tó bí rúbọ+—

  • Hébérù 11:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Àmọ́, ó ronú pé Ọlọ́run lè gbé e dìde tó bá tiẹ̀ kú, ó sì rí i gbà láti ibẹ̀ lọ́nà àpèjúwe.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́