-
2 Àwọn Ọba 2:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Nígbà tí àwọn ọmọ wòlíì tó wà ní Jẹ́ríkò rí i lókèèrè, wọ́n sọ pé: “Ẹ̀mí Èlíjà ti bà lé Èlíṣà.”+ Torí náà, wọ́n wá pàdé rẹ̀, wọ́n sì tẹrí ba mọ́lẹ̀ níwájú rẹ̀. 16 Wọ́n sọ fún un pé: “Àádọ́ta (50) géńdé ọkùnrin wà níbí pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ. Jọ̀ọ́, jẹ́ kí wọ́n lọ wá ọ̀gá rẹ. Ó lè jẹ́ pé, nígbà tí ẹ̀mí* Jèhófà gbé e, orí ọ̀kan nínú àwọn òkè tàbí àwọn àfonífojì ni ó jù ú sí.”+ Àmọ́ ó sọ pé: “Ẹ má ṣe rán wọn.”
-
-
Ìṣe 8:39Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
39 Nígbà tí wọ́n jáde nínú omi, ní kíá, ẹ̀mí Jèhófà* darí Fílípì lọ, ìwẹ̀fà náà kò sì rí i mọ́, àmọ́ ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, inú rẹ̀ sì ń dùn.
-