ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 11:24, 25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Mósè wá jáde lọ sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fún àwọn èèyàn náà. Ó sì kó àádọ́rin (70) ọkùnrin jọ lára àwọn àgbààgbà nínú àwọn èèyàn náà, ó sì mú wọn dúró yí àgọ́+ ká. 25 Jèhófà bá sọ̀ kalẹ̀ nínú ìkùukùu,*+ ó bá a+ sọ̀rọ̀, ó sì mú díẹ̀ lára ẹ̀mí+ tó wà lára rẹ̀, ó fi sára àwọn àádọ́rin (70) àgbààgbà náà lọ́kọ̀ọ̀kan. Gbàrà tí ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bíi wòlíì,*+ àmọ́ wọn ò tún ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.

  • Nọ́ńbà 27:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Mú Jóṣúà ọmọ Núnì, ọkùnrin tí ẹ̀mí wà nínú rẹ̀, kí o sì gbé ọwọ́ rẹ lé e.+

  • Nọ́ńbà 27:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Kí o sì fún un+ lára àṣẹ* tí o ní, kí gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa gbọ́ tirẹ̀.+

  • 2 Àwọn Ọba 2:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n sọdá, Èlíjà sọ fún Èlíṣà pé: “Béèrè ohun tí o bá fẹ́ kí n ṣe fún ọ kí Ọlọ́run tó mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” Torí náà, Èlíṣà sọ pé: “Jọ̀ọ́, fún mi ní ìpín*+ méjì nínú ẹ̀mí rẹ.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́