ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 45:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Ẹ kóra jọ, kí ẹ sì wá.

      Ẹ jọ sún mọ́ tòsí, ẹ̀yin tí ẹ yè bọ́ látinú àwọn orílẹ̀-èdè.+

      Wọn ò mọ nǹkan kan, àwọn tó ń gbé ère gbígbẹ́ kiri,

      Tí wọ́n sì ń gbàdúrà sí ọlọ́run tí kò lè gbà wọ́n.+

  • Jeremáyà 10:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  5 Wọ́n dà bí aṣọ́komásùn tó wà nínú oko kùkúńbà,* wọn ò lè sọ̀rọ̀;+

      Ńṣe là ń gbé wọn, torí wọn ò lè rìn.+

      Má bẹ̀rù wọn, torí wọn ò lè pani lára,

      Bẹ́ẹ̀ ni wọn ò lè ṣeni lóore kankan.”+

  • Dáníẹ́lì 5:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe lo gbé ara rẹ ga sí Olúwa ọ̀run,+ o sì ní kí wọ́n kó àwọn ohun èlò ilé rẹ̀ wá fún ọ.+ Ìwọ àti àwọn èèyàn rẹ pàtàkì, àwọn wáhàrì rẹ àti àwọn ìyàwó rẹ onípò kejì wá fi wọ́n mu wáìnì, ẹ sì ń yin àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi fàdákà, wúrà, bàbà, irin, igi àti òkúta ṣe, àwọn ọlọ́run tí kò rí nǹkan kan, tí wọn ò gbọ́ nǹkan kan, tí wọn ò sì mọ nǹkan kan.+ Àmọ́ o ò yin Ọlọ́run tí èémí rẹ+ àti gbogbo ọ̀nà rẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀.

  • Hábákúkù 2:18, 19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Kí ni àǹfààní ère,

      Nígbà tó jẹ́ pé èèyàn ló gbẹ́ ẹ?

      Kí ni àǹfààní ère onírin* àti olùkọ́ èké,

      Tí ẹni tó ṣe é bá tiẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e,

      Tó ṣe àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí, tí kò lè sọ̀rọ̀?+

      19 O gbé, ìwọ tí ò ń sọ fún igi pé: “Dìde!”

      Tàbí fún òkúta tí kò lè sọ̀rọ̀ pé: “Gbéra nílẹ̀! Máa kọ́ wa!”

      Wò ó! Wúrà àti fàdákà ni wọ́n fi bò ó,+

      Kò sì sí èémí kankan nínú rẹ̀.+

  • 1 Kọ́ríńtì 8:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Ní báyìí, ní ti jíjẹ oúnjẹ tí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà, a mọ̀ pé òrìṣà kò jẹ́ nǹkan kan+ nínú ayé àti pé kò sí Ọlọ́run míì àfi ọ̀kan ṣoṣo.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́