31 Àfi bíi pé nǹkan kékeré ni lójú rẹ̀ bó ṣe ń rìn nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì, ó tún fẹ́ Jésíbẹ́lì+ ọmọ Etibáálì, ọba àwọn ọmọ Sídónì,+ ó bẹ̀rẹ̀ sí í sin Báálì,+ ó sì ń forí balẹ̀ fún un.
4 nígbà tí Jésíbẹ́lì+ ń pa àwọn wòlíì Jèhófà,* Ọbadáyà kó ọgọ́rùn-ún [100] wòlíì, ó fi wọ́n pa mọ́ ní àádọ́ta-àádọ́ta sínú ihò, ó sì ń fún wọn ní oúnjẹ àti omi.)