-
1 Àwọn Ọba 15:25-29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Nádábù+ ọmọ Jèróbóámù di ọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún kejì Ásà ọba Júdà, ọdún méjì ló sì fi ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì. 26 Ohun búburú ló ń ṣe ní ojú Jèhófà, ó sì ń rìn ní ọ̀nà bàbá rẹ̀+ àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí bàbá rẹ̀ mú kí Ísírẹ́lì dá.+ 27 Bááṣà ọmọ Áhíjà ará ilé Ísákà dìtẹ̀ mọ́ ọn, Bááṣà sì pa á ní Gíbétónì+ tó jẹ́ ti àwọn Filísínì, nígbà tí Nádábù àti gbogbo Ísírẹ́lì dó ti Gíbétónì. 28 Bí Bááṣà ṣe pa á nìyẹn ní ọdún kẹta Ásà ọba Júdà, ó sì jọba ní ipò rẹ̀. 29 Gbàrà tí ó di ọba, ó ṣá gbogbo ilé Jèróbóámù balẹ̀. Kò ṣẹ́ alààyè kankan kù lára àwọn ará ilé Jèróbóámù; ó ní kí wọ́n pa wọ́n rẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀, Áhíjà ọmọ Ṣílò,+ sọ.
-