ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jóṣúà 20:8, 9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Ní agbègbè Jọ́dánì, lápá ìlà oòrùn Jẹ́ríkò, wọ́n yan Bésérì+ ní aginjù tó wà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú* látinú ilẹ̀ ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Rámótì+ ní Gílíádì látinú ilẹ̀ ẹ̀yà Gádì àti Gólánì+ ní Báṣánì látinú ilẹ̀ ẹ̀yà Mánásè.+

      9 Àwọn ìlú yìí ni wọ́n yàn fún gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn àjèjì tó ń gbé láàárín wọn, kí ẹnikẹ́ni tó bá ṣèèṣì pa èèyàn* lè sá lọ síbẹ̀,+ kí ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má bàa pa á kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ níwájú àpéjọ náà.+

  • 1 Àwọn Ọba 4:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Sólómọ́nì ní àwọn alábòójútó méjìlá (12) tó ń bójú tó gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n sì ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. Ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni láti pèsè oúnjẹ ní oṣù kan lọ́dún.+

  • 1 Àwọn Ọba 4:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 ọmọ Gébérì tó ń bójú tó Ramoti-gílíádì+ (tirẹ̀ ni àwọn abúlé àgọ́ Jáírì+ ọmọ Mánásè, tó wà ní Gílíádì;+ òun ló tún ni agbègbè Ágóbù,+ tó wà ní Báṣánì:+ ọgọ́ta [60] ìlú tó tóbi, tó sì ní ògiri àti ọ̀pá ìdábùú bàbà);

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́