-
2 Sámúẹ́lì 3:26, 27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Jóábù bá jáde kúrò lọ́dọ̀ Dáfídì, ó sì rán àwọn òjíṣẹ́ tẹ̀ lé Ábínérì, wọ́n mú un pa dà láti ibi kòtò omi Sáírà; ṣùgbọ́n Dáfídì kò mọ nǹkan kan nípa rẹ̀. 27 Nígbà tí Ábínérì pa dà sí Hébúrónì,+ Jóábù mú un wọnú ibì kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè láti bá a sọ̀rọ̀ ní ìdákọ́ńkọ́. Àmọ́, ibẹ̀ ni ó ti gún un ní ikùn, ó sì kú;+ èyí jẹ́ nítorí pé ó pa* Ásáhélì+ arákùnrin rẹ̀.
-