16 Èlíjà wá sọ fún ọba pé, “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘O rán àwọn òjíṣẹ́ pé kí wọ́n lọ wádìí lọ́dọ̀ Baali-sébúbù ọlọ́run Ẹ́kírónì.+ Ṣé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ni?+ Kí ló dé tí o ò fi wádìí lọ́dọ̀ rẹ̀? Torí náà, o ò ní kúrò lórí ibùsùn tí o wà yìí, torí ó dájú pé wàá kú.’”