11 Lẹ́yìn náà, Amasááyà mọ́kàn le, ó kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ sí Àfonífojì Iyọ̀,+ ó sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) lára àwọn ọkùnrin Séírì.+ 12 Àwọn ọkùnrin Júdà wá mú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) láàyè. Wọ́n kó wọn wá sí orí àpáta, wọ́n sì jù wọ́n láti orí àpáta náà, gbogbo wọn sì já jálajàla.