-
2 Kíróníkà 20:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Ní báyìí, àwọn èèyàn Ámónì àti Móábù pẹ̀lú agbègbè olókè Séírì+ ti wà níbí, àwọn tí o kò yọ̀ǹda fún Ísírẹ́lì láti gba ilẹ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti ilẹ̀ Íjíbítì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yà kúrò lọ́dọ̀ wọn, wọn ò sì pa wọ́n rẹ́.+ 11 Ní báyìí, ohun tí wọ́n fẹ́ fi san án fún wa ni pé kí wọ́n wá lé wa jáde kúrò lórí ohun ìní rẹ tí o fún wa láti jogún. +
-