ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 20:3-5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 O ò gbọ́dọ̀ ní ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.*+

      4 “O ò gbọ́dọ̀ gbẹ́ ère kankan fún ara rẹ tàbí kí o ṣe ohun* kan tó dà bí ohunkóhun lókè ọ̀run tàbí ní ayé tàbí nínú omi nísàlẹ̀.+ 5 O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún wọn tàbí kí o jẹ́ kí wọ́n tàn ọ́ láti sìn wọ́n,+ torí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí o máa sin òun nìkan ṣoṣo,+ tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ, dórí ìran kẹta àti ìran kẹrin àwọn tó kórìíra mi,

  • Ẹ́kísódù 23:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Ẹ ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún àwọn ọlọ́run wọn, ẹ má sì jẹ́ kí wọ́n mú kí ẹ sìn wọ́n, ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kí ẹ wó wọn palẹ̀, kí ẹ sì run àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn.+

  • Ẹ́kísódù 34:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún ọlọ́run míì,+ torí Jèhófà máa ń fẹ́* kí a jọ́sìn òun nìkan.* Àní, ó jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí a máa sin òun nìkan.+

  • Diutarónómì 5:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún wọn tàbí kí o jẹ́ kí wọ́n sún ọ láti sìn wọ́n,+ torí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí o máa sin òun nìkan ṣoṣo,+ tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ, dórí ìran kẹta àti ìran kẹrin àwọn tó kórìíra mi,+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́