7 Ibẹ̀ ni kí ẹ̀yin àti àwọn agbo ilé yín ti jẹun níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kí ẹ sì máa yọ̀ nínú gbogbo ohun tí ẹ bá dáwọ́ lé,+ torí Jèhófà Ọlọ́run yín ti bù kún yín.
10 Nígbà tó di ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù keje, ó ní kí àwọn èèyàn náà máa lọ sí ilé wọn, inú wọn ń dùn,+ ayọ̀ sì kún ọ̀kan wọn nítorí oore tí Jèhófà ṣe fún Dáfídì àti Sólómọ́nì pẹ̀lú Ísírẹ́lì àwọn èèyàn rẹ̀.+
12 Torí náà, gbogbo àwọn èèyàn náà lọ, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu, wọ́n fi oúnjẹ ránṣẹ́ sí àwọn míì, inú wọn sì ń dùn gan-an,+ nítorí ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ yé wọn.+