34 Yàtọ̀ síyẹn, Fáráò Nẹ́kò fi Élíákímù ọmọ Jòsáyà jọba ní ipò Jòsáyà bàbá rẹ̀, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pa dà sí Jèhóákímù; àmọ́ ó mú Jèhóáhásì wá sí Íjíbítì,+ ibẹ̀ ló sì kú sí nígbẹ̀yìn.+
11 “Èyí ni ohun tí Jèhófà sọ nípa Ṣálúmù*+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà tó ń jọba nípò Jòsáyà bàbá rẹ̀,+ ẹni tó jáde kúrò ní ibí yìí: ‘Kò ní pa dà mọ́. 12 Nítorí ibi tí wọ́n mú un lọ ní ìgbèkùn ló máa kú sí, kò sì ní rí ilẹ̀ yìí mọ́.’+