-
Ìsíkíẹ́lì 17:12-15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 “Jọ̀ọ́ sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé náà pé, ‘Ṣé ẹ ò mọ ohun tí nǹkan wọ̀nyí túmọ̀ sí ni?’ Sọ pé, ‘Wò ó! Ọba Bábílónì wá sí Jerúsálẹ́mù, ó mú ọba rẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì mú wọn pa dà wá sí Bábílónì.+ 13 Ó tún mú ọ̀kan lára àwọn ọmọ* ọba,+ ó bá a dá májẹ̀mú, ó sì mú kó búra.+ Ó wá kó àwọn tó gbajúmọ̀ ní ilẹ̀ náà lọ,+ 14 kó lè rẹ ìjọba náà wálẹ̀, kó má lè dìde, kó lè jẹ́ pé tó bá ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ nìkan ni ìjọba náà á fi lè máa wà nìṣó.+ 15 Àmọ́ níkẹyìn, ọba náà ṣọ̀tẹ̀ sí i,+ ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ sí Íjíbítì, kí wọ́n lè fún un ní àwọn ẹṣin+ àti ọmọ ogun púpọ̀.+ Ṣé ó máa ṣàṣeyọrí? Ǹjẹ́ ẹni tó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí á bọ́ lọ́wọ́ ìyà? Ṣé ó lè da májẹ̀mú kó sì mú un jẹ?’+
-