ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 26:40
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 40 Wọ́n á wá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ara wọn+ àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá wọn pẹ̀lú ìwà àìṣòótọ́ àwọn bàbá wọn, wọ́n á sì gbà pé àwọn ti hùwà àìṣòótọ́ torí wọ́n kẹ̀yìn sí mi.+

  • Ẹ́sírà 9:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Mo sọ pé: “Ìwọ Ọlọ́run mi, ojú ń tì mí, ara sì ń tì mí láti gbé ojú mi sókè sí ọ, ìwọ Ọlọ́run mi, nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ti pọ̀ gan-an lórí wa, ẹ̀bi wa sì ti ga dé ọ̀run.+

  • Nehemáyà 1:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 jọ̀ọ́, jẹ́ kí etí rẹ ṣí sílẹ̀, kí o sì bojú wò mí láti gbọ́ àdúrà ìránṣẹ́ rẹ, tí mò ń gbà sí ọ lónìí. Tọ̀sántòru ni mò ń gbàdúrà+ nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìránṣẹ́ rẹ, gbogbo ìgbà yẹn ni mò ń jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì dá sí ọ. A ti ṣẹ̀, àtèmi àti ilé bàbá mi.+

  • Sáàmù 106:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 A ti dẹ́ṣẹ̀ bí àwọn baba ńlá wa;+

      A ti ṣe ohun tí kò dáa; a ti hùwà burúkú.+

  • Dáníẹ́lì 9:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe ohun tí kò dáa, a ti hùwà burúkú, a sì ti ṣọ̀tẹ̀;+ a ti kọ àwọn àṣẹ rẹ àti àwọn ìdájọ́ rẹ sílẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́