62 Ọba àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ wá rú ẹbọ púpọ̀ níwájú Jèhófà.+ 63 Sólómọ́nì rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ sí Jèhófà: Ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) màlúù àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn ni ó fi rúbọ. Bí ọba àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣayẹyẹ ṣíṣí ilé Jèhófà+ nìyẹn.