-
Diutarónómì 4:25, 26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 “Tí ẹ bá bí àwọn ọmọ, tí ẹ sì ní àwọn ọmọ ọmọ, tí ẹ sì ti pẹ́ ní ilẹ̀ náà, àmọ́ tí ẹ wá ṣe ohun tó lè fa ìparun, tí ẹ gbẹ́ ère+ èyíkéyìí, tí ẹ sì ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà Ọlọ́run yín láti mú un bínú,+ 26 mo fi ọ̀run àti ayé ṣe ẹlẹ́rìí ta kò yín lónìí, pé ó dájú pé kíákíá lẹ máa pa run ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọdá Jọ́dánì láti lọ gbà. Ẹ ò ní pẹ́ níbẹ̀, ṣe lẹ máa pa run pátápátá.+
-
-
2 Àwọn Ọba 17:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Jèhófà kọ gbogbo àtọmọdọ́mọ Ísírẹ́lì sílẹ̀, ó dójú tì wọ́n, ó sì fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn tó ń kóni lẹ́rù, títí ó fi lé wọn kúrò níwájú rẹ̀.
-