-
1 Àwọn Ọba 9:20-23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Ní ti gbogbo èèyàn tó ṣẹ́ kù lára àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ tí wọn kì í ṣe ara àwọn èèyàn Ísírẹ́lì,+ 21 àwọn àtọmọdọ́mọ wọn tó ṣẹ́ kù sí ilẹ̀ náà, ìyẹn àwọn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lè pa run, Sólómọ́nì ní kí wọ́n máa ṣíṣẹ́ fún òun bí ẹrú títí di òní yìí.+ 22 Àmọ́ Sólómọ́nì kò fi ọmọ Ísírẹ́lì kankan ṣe ẹrú,+ àwọn ló fi ṣe jagunjagun, ìránṣẹ́, ìjòyè, olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun, olórí àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ti àwọn agẹṣin rẹ̀. 23 Ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé àádọ́ta (550) olórí àwọn alábòójútó ló ń darí iṣẹ́ Sólómọ́nì, àwọn ló sì ń darí àwọn òṣìṣẹ́.+
-