-
1 Àwọn Ọba 9:26-28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Ọba Sólómọ́nì tún ṣe ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun ní Esioni-gébérì,+ tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Élótì, ní èbúté Òkun Pupa ní ilẹ̀ Édómù.+ 27 Hírámù kó ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun+ rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ òkun tó mọṣẹ́, láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì. 28 Wọ́n lọ sí Ófírì,+ wọ́n sì kó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ogún (420) tálẹ́ńtì wúrà láti ibẹ̀ wá fún Ọba Sólómọ́nì.
-