-
1 Àwọn Ọba 14:25-28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Ní ọdún karùn-ún Ọba Rèhóbóámù, Ṣíṣákì+ ọba Íjíbítì wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù.+ 26 Ó kó àwọn ìṣúra ilé Jèhófà àti ìṣúra ilé* ọba.+ Gbogbo nǹkan pátá ló kó, títí kan gbogbo apata wúrà tí Sólómọ́nì ṣe.+ 27 Nítorí náà, Ọba Rèhóbóámù ṣe àwọn apata bàbà láti fi rọ́pò wọn, ó sì fi wọ́n sí ìkáwọ́ àwọn olórí ẹ̀ṣọ́* tó ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ọba. 28 Nígbàkigbà tí ọba bá wá sí ilé Jèhófà, àwọn ẹ̀ṣọ́ á gbé àwọn apata náà, lẹ́yìn náà, wọ́n á dá wọn pa dà sí yàrá ẹ̀ṣọ́.
-