-
2 Àwọn Ọba 18:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Nítorí náà, Hẹsikáyà ọba Júdà ránṣẹ́ sí ọba Ásíríà ní Lákíṣì pé: “Èmi ni mo jẹ̀bi. Má ṣe bá mi jà mọ́, ohunkóhun tí o bá ní kí n san ni màá san.” Ni ọba Ásíríà bá bu ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) tálẹ́ńtì* fàdákà àti ọgbọ̀n (30) tálẹ́ńtì wúrà lé Hẹsikáyà ọba Júdà. 15 Torí náà, Hẹsikáyà fi gbogbo fàdákà tí wọ́n rí ní ilé Jèhófà àti ní àwọn ibi ìṣúra ilé* ọba+ lélẹ̀.
-
-
2 Àwọn Ọba 24:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Jèhóákínì ọba Júdà jáde lọ bá ọba Bábílónì,+ òun àti ìyá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀;+ ọba Bábílónì sì mú un lẹ́rú ní ọdún kẹjọ ìṣàkóso rẹ̀.+ 13 Lẹ́yìn náà, ó kó gbogbo ìṣúra ilé Jèhófà àti ìṣúra ilé* ọba jáde kúrò.+ Gbogbo nǹkan èlò wúrà tí Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì ṣe sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà+ ni ó gé sí wẹ́wẹ́. Èyí ṣẹlẹ̀ bí Jèhófà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́lẹ́.
-