24 Jòsáyà tún gbá àwọn abẹ́mìílò dà nù àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́,+ àwọn ère tẹ́ráfímù,+ àwọn òrìṣà ẹ̀gbin pẹ̀lú gbogbo ohun ìríra tó fara hàn ní ilẹ̀ Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù, kí ó lè mú àwọn ọ̀rọ̀ Òfin+ tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé tí àlùfáà Hilikáyà rí ní ilé Jèhófà ṣẹ.+