ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 19:31
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 31 “‘Ẹ má tọ àwọn abẹ́mìílò lọ.+ Ẹ má sì wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn woṣẹ́woṣẹ́,+ kí wọ́n má bàa sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.

  • Diutarónómì 18:10, 11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Ẹnì kankan láàárín yín ò gbọ́dọ̀ sun ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ nínú iná,+ kò gbọ́dọ̀ woṣẹ́,+ kò gbọ́dọ̀ pidán,+ kò gbọ́dọ̀ wá àmì ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀,+ kò gbọ́dọ̀ di oṣó,+ 11 kò gbọ́dọ̀ fi èèdì di àwọn ẹlòmíì, kò gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò+ tàbí woṣẹ́woṣẹ́,+ kò sì gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ òkú.+

  • 2 Àwọn Ọba 21:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Ọmọ ọdún méjìlá (12) ni Mánásè+ nígbà tó jọba, ọdún márùndínlọ́gọ́ta (55) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Héfísíbà.

  • 2 Àwọn Ọba 21:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Ó sun ọmọ rẹ̀ nínú iná; ó ń pidán, ó ń woṣẹ́,+ ó sì yan àwọn abẹ́mìílò àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́.+ Ohun búburú tó pọ̀ gan-an ló ṣe lójú Jèhófà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú un bínú.

  • Àìsáyà 8:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Tí wọ́n bá sì sọ fún yín pé: “Ẹ lọ wádìí lọ́wọ́ àwọn abẹ́mìílò tàbí àwọn woṣẹ́woṣẹ́, àwọn tó ń ké ṣíoṣío, tí wọ́n sì ń jẹnu wúyẹ́wúyẹ́,” ṣebí ọwọ́ Ọlọ́run wọn ló yẹ kí àwọn èèyàn ti lọ wádìí? Ṣé ó yẹ kí wọ́n lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ òkú nítorí alààyè?+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́